Wt/yo/ọkùnrin

< Wt‎ | yo
Wt > yo > ọkùnrin

Yorùbá edit

Ọ̀rọ̀ orúkọ edit

Ọkùnrin jẹ́ ọ̀rọ̀-orúkọ [1] fún ohun abẹ̀mí akọ yálà ó jẹ́ ọmọdé tabí àgbà tí àtọ̀ rẹ̀ lè dọmọ lára obìnrin. Tí a bá sọ wípé ọkùnrin ní inú èdè Yorùbá ohun tí a ń sọ nípa rẹ̀ ni ènìyàn tí ó jẹ́ akọ; bákan náà ni àwọn ẹ̀dá tókù bíi ẹranko, kòkòrò ati bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ náà ní akọ nínú wọn. Àmọ́, akìí pe ohunkóhun míràn nínú èdè Yorùbá ní ọkùnrin, àyàfi ènìyàn nìkan. Ọkùnrin ni ó ma ń gbé ìyàwó sílé tí ó sì ma ń ṣe ìtọ́jú aya rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ.

Àpẹẹrẹ:

  • ọmọ ọkùnrin ni Táyé bí.
  • Ọkùnrin gidi ni babá mi Àdìó

Ní èdè míràn edit

Èdè Gẹ̀ẹ́sì edit

Àwọn ìtọ́kasí edit

Template:Wt/yo/reflist

  1. Template:Wt/yo/cite web